30. (Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì pa Ábínérì, nítorí pé òun ti pa Áṣáhélì arákùnrin wọn ní Gíbíónì ní ogun.)
31. Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.
32. Wọ́n sì sin Ábínérì ní Hébírónì: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sunkùn ní ibojì Ábínérì; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sunkún.
33. Ọba sì sọkún lórí Ábínérì, ó sì wí pé,“Ǹjẹ́ Ábínérì; yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?