23. “Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì—ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn,ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n.Wọ́n yára ju àṣá lọ,wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.
24. “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì,ẹ sunkún lórí Ṣọ́ọ̀lù,ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín,ẹni tí ó fí wúrà sí ara aṣọ yín.
25. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun!Jónátánì, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.
26. Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jónátanì arákùnrin mi;ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi.Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu,ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.
27. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú!Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”