23. Àwọn ìránṣẹ́ Ámónì dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárin ilé rẹ̀.
24. Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì fi Jòsíáyà ọmọ rẹ̀ jọba ní àyè rẹ̀.
25. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Ámónì àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà?
26. Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Úṣà. Jòṣíáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.