2 Ọba 21:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Mánásè sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Úṣà Ámónì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.

19. Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jọba. Orúkọ bàbá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Méṣúlémétì ọmọbìnrin Hárúsì: ó wá láti Jótíbà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.

20. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Mánásè ti ṣe.

2 Ọba 21