2 Ọba 10:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ìlà-oòrùn ti Jọ́dánì ni gbogbo ilẹ̀ ti Gílíádì (ẹ̀kún ilẹ̀ ti Gádì, Rúbẹ́nì, àti Mánásè) láti Áróérì, tí ó wà létí Ánónì Gọ́ọ́jì láti ìhà Gílíádì sí Básánì.

34. Fún ti òmìíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jéhù, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

35. Jéhù sin mi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Ṣamáríà Jéhóáhásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

36. Àkókò tí Jéhù fi jọba lórí Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.

2 Ọba 10