1. Àwa há tún bẹ̀rẹ̀ làti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí làti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe?
2. Ẹ̀yin fúnara yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.
3. Ẹ̀yin sì ń fi hàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kírísítì ni yín, kì í ṣe èyí tí a si fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè; kì í ṣe nínú wàláà okútà bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ènìyàn.