1. Èmi kò lè sàì sògo bí kò tilẹ̀ ve àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípayá ti Olúwa fihàn mí.
2. Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kírísítì ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yin, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run kẹta.
3. Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀.
4. Pé a gbé e lọ sókè sí Párádísè, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ.
5. Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkáraami èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi.
6. Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi.
7. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Sátanì láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá.
8. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi.
9. Òun sì wí fún mi pé, “Oore ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fí ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kírísítì lè máa gbé inú mi.