2 Kíróníkà 8:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò parun àwọn ni Sólómónì bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.

9. Ṣùgbọ́n Solómónì kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún Ísírẹ́lì, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́.

10. Wọ́n sì tún jẹ́ olórí alásẹ fún ọba Sólómónì àádọ́ta ó lé nígba àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn (250).

11. Sólómónì gbé ọmọbìnrin Fáráò sókè láti ìlú Dáfídì lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

12. Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Sólómónì sì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Olúwa,

13. Nípa ìlànà ojojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pa lásẹ láti ọ̀dọ̀ Mósè wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àkàrà àìwú, ní àjọ ọ̀ṣẹ̀ méje àti àjọ ìpàgọ́.

2 Kíróníkà 8