2 Kíróníkà 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Sólómónì kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnrarẹ̀.

2. Sólómónì tún ìlú tí Hírámù ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀.

3. Nígbà náà Sólómónì lọ sí Hámátì Sóbà ó sì borí rẹ̀.

4. Ó sì tún kọ́ Tádímórì ní ihà àti gbogbo ìlú ìsúra tí ó ti kọ́ ní Hámátì.

5. Ó sì tún kọ́ òkè Bẹti Hórónì àti ìsàlẹ̀ Bétì Hórónì gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá-ìdábùú.

2 Kíróníkà 8