2 Kíróníkà 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Sólómonì wí pé, “Olúwa ti sọ wí pé òun yóò máa gbé nínú ìkùku tí ó ṣú biribiri;

2. ṣùgbọ́n èmi ti kọ́ tẹ́ḿpìlì dáradára fún ọ ibi tí ìwọ yóò máa gbé títí láé.”

3. Ní ìgbà tí gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì dúró níbẹ̀, ọba yíjú padà ó sì fi ìbùkún fún gbogbo wọn.

4. Nígbà náà ni ó sì wí pé:“Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dáfídì baba mi ṣẹ. Nitorí tí ó wí pé,

5. ‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Ísirẹ́lì ènìyàn mi.

6. Ṣùgbọ́n nísinyìí èmi ti yan Jérúsálẹ́mù, kí orukọ mi leè wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dáfídì láti jọba lórí Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’

7. “Baba mi Dáfídì ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹ́ḿpìlì fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

2 Kíróníkà 6