2 Kíróníkà 35:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Jeremáyà sì pohùn réré ẹkún fún Jósíà, gbogbo àwọn akọrin ọkùnrin àti gbogbo àwọn akọrin obìnrin sì ń sọ ti Jósíà nínú orin ẹkún wọn títí di òní. Èyí sì di àṣà ní Jérúsálẹ́mù, a sì kọọ́ sínú àwọn orin ẹkún.

26. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Jósíà àti ìwà rere rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti kọ sínu ìwé òfin Olúwa.

27. Gbogbo iṣẹ́ náà, àti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Ísírẹ́lì àti Júdà.

2 Kíróníkà 35