21. Ọba Ùsíá sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé ọ̀tọ̀ adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ile Olúwa. Jótamù ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
22. Ìyòókù iṣẹ́ ìjọba Ùsía láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Ìsàíà ọmọ Ámósì.
23. Ùsáyà sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀,” Jótamù ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.