1. Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìya rẹ̀ ni Ṣíbíà ti Béríṣébà.
2. Jóásì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jéhóiádà àlùfáà.
3. Jéhóiádà yan ìyàwó méjì fún-un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.
4. Ní àkókò kan, Jóásì pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.
5. Ó pe Àwọn Àlùfáà àti àwọn ará Léfì jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Júdà, kí ẹ sì gba owó ìtọ̀sì lati ọwọ́ gbogbo Ísírẹ́lì láti fi tún ilé Ọlọ́run ṣe, ṣé nísinsìn yìí” Ṣùgbọ́n àwọn ará Léfì kò ṣe é lẹ́ẹ́kan naà.