2 Kíróníkà 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jóásì jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìya rẹ̀ ni Ṣíbíà ti Béríṣébà.

2. Jóásì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa ní gbogbo àkókò Jéhóiádà àlùfáà.

3. Jéhóiádà yan ìyàwó méjì fún-un, ó sì ní àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.

4. Ní àkókò kan, Jóásì pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.

2 Kíróníkà 24