2 Kíróníkà 2:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lébanónì tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Jópà. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.”

17. Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe; a sì ka iye wọn sí (153,600) ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n.

18. Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́.

2 Kíróníkà 2