2 Kíróníkà 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsin yìí Jéhóṣáfátì sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Áhábù nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀.

2. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Áhábù lálejò ní Saaríà. Áhábù sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramótì Gílíádì.

3. Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jèhóṣáfátì, ọba Júdà pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Rámótì Gílíádì?”Jehóṣáfátì sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ ninú ogun naà”

4. Ṣùgbọ́n Jehóṣáfátì náà sì tún wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

5. Bẹ́ẹ̀ ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì papọ̀, irínwó (4,000) ọkùnrin ó sì bi wọ́n pé, “Kí àwa kí lọ sí ogun Rámótì Gélíádì tàbi kí èmi kí ó jọ̀wọ́ rẹ?”“Lọ,” wọ́n dáhùn, “nítorí tí Olúwa yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”

2 Kíróníkà 18