2 Kíróníkà 17:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Èkejì Jéhósáfátì olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá ọkùnrin (280,000);

16. Àtẹ̀lé Ámásíà ọmọ Síkírì, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000).

17. Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì:Élíádà, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;

18. Àtẹ̀lé Jéhósábádì, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun.

19. Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwáju ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Júdà.

2 Kíróníkà 17