1. Réhóbóámù sì lọ sí Ṣékémù nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba.
2. Nígbà tí Jéróbóámù ọmọ Nébátì gbọ́ èyí ó wà ní Éjíbítì, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Sólómónì ó sì padà láti Éjíbítì.
3. Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránsẹ́ sí Jéróbóámù àti òun àti gbogbo àwọn Ísírẹ́lì lọ sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù wọ́n sì wí fún pé:
4. “Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”