12. Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”
13. Nígbà náà ni Sólómónì sì ti ibi gígá Gíbíónì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti iwájú àgọ́ ìpàde. Ó sì jọba lórí Ísírẹ́lì.
14. Sólómónì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹsin jọ, ó sì ní ẹgbàáje kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàafà ẹlẹ́sin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù
15. ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jérúsálẹ́mù bí òkúta, àti Kédárì ó pọ̀ bí igi Síkámórè ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.
16. Àwọn ẹsin Sólómónì ní a gbà láti ìlú òkèrè Éjíbítì àti láti kúè oníṣòwò ti ọba ni ó rà wọ́n láti Kúè.
17. Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Éjíbítì. Fún ọgọ́rùn ún mẹ́fà Sékélì (6,000) fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì-ó-dínláàdọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hítì àti ti àwọn ará Árámíà.