1. Pọ́ọ̀lù, Sílásì àti Tímótíù.A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jésù Kírísítì.Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kírísítì kí ó jẹ́ tiyín.
2. Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú.
3. A ń rántí lí àìsinmi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Bàbá iṣẹ́ ìgbàgbọ́yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró sinsin ìretí yín nínú Jésù Kírísítì Olúwa wa.
4. Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀.
5. Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìn rere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrin yín nítorí yín.
6. Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mi Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.