1 Sámúẹ́lì 28:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì rí ogun àwọn Fílístínì náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

6. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Úrímù tàbí nípa àwọn wòlíì.

7. Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mi abókúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Ẹ́ńdórì tí ó ní ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀.”

8. Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

1 Sámúẹ́lì 28