1 Sámúẹ́lì 27:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dáfídì sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Fílístínì: yóò sú Ṣọ́ọ̀lù láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì: èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”

2. Dáfídì sì dìde, ó sì rékọjá, òun pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọmọkùnrin tí o ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Ákíṣì, ọmọ Máókì, ọba Gátì.

3. Dáfídì sì bá Ákíṣì jókòó ní Gátì, òun, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ, olúkúlùkù wọn pẹ̀lú ará ilé rẹ̀; Dáfídì pẹ̀lú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, Áhínóámù ara Jésréélì, àti Ábígáílì ará Kámẹ́lì aya Nábálì.

4. A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, Dáfídì sá lọ si Gátì: òun kò sì tún wá á kiri mọ́.

5. Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀: èéṣé tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

6. Ákíṣì sí fi Síkílágì fún un ní ijọ́ náà nítorí náà ni Síkílágì fí dí ọba Júdà títí ó fí dì òní yìí.

1 Sámúẹ́lì 27