1 Sámúẹ́lì 25:39-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Dáfídì sì gbọ́ pé Nábálì kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa tí o gbéjà gígàn mi láti ọwọ́ Nábálì wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: Olúwa sì yí ikà Nábálì sí orí òun tìkárarẹ̀.”Dáfídì sì ránṣẹ́, ó sì ba Ábígáílì sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.

40. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì lọ sọ́dọ̀ Ábígáílì ni Kamẹ́lì, wọn sì sọ fún un pé, “Dáfídì rán wá si ọ láti mu ọ ṣe aya rẹ̀.”

41. Ó sì dìde, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ó jẹ́ ìránṣẹ́ kan láti máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi.”

42. Ábígáílì sì yára, ó sì dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn iránṣẹ́bìnrin rẹ̀ márùnún sì tẹ̀lé e lẹ́yìn; oun sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì, o sì wá di aya rẹ̀.

43. Dáfídì sì mú Áhínóámù ará Jésírẹ́lì; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀.

44. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti fi Míkálì ọmọ rẹ̀ obìnrin aya Dáfídì, fún Fátíélì ọmọ Láìsi tí i ṣe ara Gálímù.

1 Sámúẹ́lì 25