35. Èmi yóò dìde fún ara mi láti gbé àlùfáà olódodo dìde fún ara mi ẹni tí yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà ní ọkàn mi àti inú mi: Èmi yóò fi ẹṣẹ̀ ilé rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in òun yóò sì ṣe òjíṣẹ́ níwájú ẹni òróró mi ní ọjọ́ gbogbo.
36. Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”