21. Wọ́n sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọtẹ́lẹ̀.
22. Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rámà ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Ṣékù. Ó sì béèrè, “Níbo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà?”Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Náíótì ní Rámà.”
23. Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí Náíótì ni Rámà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Náíótì.
24. Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ níwájú Sámúẹ́lì. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”