53. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì padà láti máa lé àwọn ará Fílístínì, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́.
54. Dáfídì gé orí Fílístínì ó sì gbé e wá sí Jérúsálẹ́mù, ó sì kó àwọn ohun ìjà Fílístínì sìnú àgọ́ tirẹ̀.
55. Bí Ṣọ́ọ̀lù sì ti wo Dáfídì bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Fílístínì, ó wí fún Ábínérì, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?”Ábínérì dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”
56. Ọba sì wí pé, “Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe.”
57. Gbàrà tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Fílístínì, Ábínérì sì mú u wá ṣíwájú u Ṣọ́ọ̀lù, orí Fílístínì sì wà ní ọwọ́ Dáfídì.
58. Ṣọ́ọ̀lù béèrè pé, “Ọmọdékùnrin, ọmọ ta ni ọ́?”Dáfídì dáhùn pé, “Èmi ni ọmọ ìránṣẹ́ rẹ Jésè ti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.”