1 Sámúẹ́lì 10:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”

20. Nígbà Sámúẹ́lì mú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.

21. Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì. Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,

1 Sámúẹ́lì 10