1 Pétérù 3:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó farasìn ní ọkàn, nínú ọ̀sọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

5. Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbaànì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi sẹ ara wọn lọ́sọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ tiwọn.

6. Gẹ́gẹ́ bí Sárà ti gbọ́ ti Ábúráhámù, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

7. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi Òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.

8. Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀

9. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogun ìbùkún.

10. Nítorí,“Ẹni tí yóò bá fẹ ìyè,ti yóò sì rí ọjọ́ rere,kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:

11. Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.

1 Pétérù 3