1 Pétérù 1:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”

17. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù.

18. Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.

19. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n ani ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

1 Pétérù 1