22. Sólómónì ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Ábíságì ará Súnémù fún Àdóníjà! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ni í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Ábíátarì àlùfáà àti fun Jóábù ọmọ Sérúíà!”
23. Nígbà náà ni Sólómónì ọba fi Olúwa búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí níyà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Àdóníjà kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí!
24. Àti nísinsìnyí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láàyè ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dáfídì àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Àdóníjà!”
25. Sólómónì ọba sì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Jéhóíádà, ó sì kọlu Àdóníjà, ó sì kú.
26. Ọba sì wí fún Ábíátarì àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Ánátótì, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsìn yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa níwájú Dáfídì baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.”
27. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì yọ Ábíátarì kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Élì ní Ṣílò ṣẹ.
28. Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Jóábù, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Àdóníjà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Ábúsálómù, ó sì sá lọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú.
29. A sì sọ fún Sólómónì ọba pé Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Sólómónì pàṣẹ fún Bénáyà ọmọ Johóíadà pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”