1. Sì kíyèsii, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Júdà sí Bétélì nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jéróbóámù sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná.
2. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsíàh ní ilé Dáfídì. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga yìí tí ó ń mú ọrẹ wá síbẹ̀, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”
3. Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé: “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsii, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”