4. Bí Sólómónì sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.
5. Ó tọ Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì lẹ́yìn, àti Mílíkómì òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.
6. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.
7. Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jérúsálẹ́mù, Sólómónì kọ́ ibi gíga kan fún Kémósì, òrìṣà ìríra Móábù, àti fún Mólékì, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ámónì.
8. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rúbọ fún òrìṣà wọn.
9. Olúwa bínú sí Sólómónì nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.
10. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Sólómónì kí ó má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Sólómónì kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.
11. Nítorí náà Olúwa wí fún Sólómónì pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmìíràn.