1 Kọ́ríńtì 6:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ yan àwọn tí ó kéré jù nínú ìjọ láti dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.

5. Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín, Ṣe ó see se kí a máa rín ẹnìkan láàrin yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe idájọ́ èdè àìyedè láàrin àwọn onígbàgbọ́?

6. Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.!

7. Ǹjẹ́ nísinsinyìí, àbùkù ni fún un yín pátapáta pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kí ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kí ní dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?

8. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.

1 Kọ́ríńtì 6