1 Kíróníkà 9:4-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Hútayì ọmọ Ámíhúdì, ọmọ Ómírì, Ọmọ Ímírì, ọmọ Bánì, ìran ọmọ Fárésì ọmọ Júdà.

5. Tí ará Ṣílò:Ásáíà àkọ́bí àti àwọn ọmọ Rẹ̀.

6. Níti ará Ṣérà:JégúélìÀwọn ènìyàn láti júdà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).

7. Níti ará:Ṣálù ọmọ Mésúlámì, ọmọ Hódáfíà; ọmọ Hásénúà;

8. Íbínéíà ọmọ Jéróhámù; Élà ọmọ Húṣì, ọmọ Míkírì àti Mésúlámù ọmọ Ṣéfátíyà; ọmọ Régúélì, ọmọ Íbíníjà.

9. Àwọn ènìyàn láti Bẹ́ńjámínì gẹ́gẹ́ bí a ti se kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rùn ún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.

10. Ní ti àwọn àlùfáà:Jédáíà; Jéhóíáríbì; Jákínì;

11. Áṣáríyà ọmọ Hílíkíyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókù, ọmọ Méráíótù, ọmọ Áhítúbì, onísẹ́ tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

12. Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Páṣúrì, ọmọ Málíkíjà; àti Másáì ọmọ Ádíélì, ọmọ Jáhíṣérà, ọmọ Mésúlámù ọmọ Méṣílémítì, ọmọ Ímérì

13. Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.

14. Níti àwọn ará Léfì:Ṣémáíà ọmọ Hásíhúbì, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíà ará Mérárì:

1 Kíróníkà 9