52. Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,
53. Ṣádókù ọmọ Rẹ̀àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.
54. Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):
55. A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
56. Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.
57. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,
58. Hílénì Débírì,
59. Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
60. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.
61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.
62. Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.