50. Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Árónì:Élíásérì ọmọ Rẹ̀. Fínéhásì ọmọ Rẹ̀,Ábísúà ọmọ Rẹ̀,
51. Búkì ọmọ Rẹ̀,Húṣì ọmọ Rẹ̀. Ṣéráhíà ọmọ Rẹ̀,
52. Méráíótì ọmọ Rẹ̀, Ámáríyà ọmọ Rẹ̀,Áhítúbì ọmọ Rẹ̀,
53. Ṣádókù ọmọ Rẹ̀àti Áhímásì ọmọ Rẹ̀.
54. Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbégbé wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Árónì lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kóhátítè, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ ti wọn):
55. A fún wọn ní Hébírónì ní Júdà pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
56. Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún kelẹ́bù ọmọ Jéfúnénì.
57. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Árónì ni a fún ní Hébírónì (ìlú ti ààbò), àti Líbínà, Játírì, Éṣitémóà,
58. Hílénì Débírì,
59. Áṣánì, Júlà àti Bétí-Ṣéméṣì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ Rẹ̀.
60. Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Béńjámínì, a fún wọn ní Gíbíónì, Gébà, Álémétì àti Ánátótì lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrin àwọn ẹ̀yà kóháhítè jẹ́ mẹ́talá ní gbogbo Rẹ̀.
61. Ìyòókù àwọn ìran ọmọ Kóháhítì ní a pín ìlú mẹ́wá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè.
62. Àwọn ìran ọmọ Géríṣómù, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Íṣákárì, Áṣérì àti Náfítalì, àti láti apá ẹ̀yà Mánásè tí ó wà ní Básánì.
63. Àwọn ìran ọmọ Mérárì, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Gádì àti Ṣébúlúní.
64. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún àwọn ará Léfì ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
65. Láti ẹ̀yà Júdà, Síméónì àti Bẹ́ńjámínì ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
66. Lára àwọn ìdílé Kóhátì ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Éfúráímù gẹ́gẹ́ bí ìlú agbégbé wọn.