1 Kíróníkà 4:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Aya Rẹ̀ Jéhúdijà sì bí Jérédì baba Gédórì, Hébérì baba sókè àti Jékútíẹ́lì bàbá Sánóà. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin ọmọ Bítíà ẹni ti Mérédì ti fẹ́.

19. Àwọn ọmọ aya Hódíyà arábìnrin Náhámù:Baba Kéílà ará Gárímì, àti Ésítémóà àwọn ará Mákà.

20. Àwọn ọmọ Símónì:Ámónì, Rínà, Beni-Hánánì àti Tílónì.Àwọn ọmọ Íṣì:Ṣóhítì àti Beni-Sóhétì.

21. Àwọn ọmọ Ṣélà ọmọ Júdà:Érì baba Lékà, Ládà baba Máréṣà àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń wun aṣọ oníṣẹ́ ní Bẹti-Áṣíbéà.

1 Kíróníkà 4