1 Kíróníkà 29:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àti fún ọmọ mi Sólómónì ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.”

20. Dáfídì sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, Nísinsìn yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín. Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.

21. Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ ọrẹ ṣíṣun sí i: ẹgbẹ̀rún kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì.

22. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.Nígbà náà wọ́n yan Sólómonì ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Ṣádókù láti ṣe àlùfáà.

23. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò bàbá a Rẹ̀ Dáfídì. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24. Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dáfídì tẹrí ara wọn ba fún ọba Sólómónì.

25. Olúwa gbé Solómónì ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọlá ńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú Rẹ̀ tí ó jẹ lórí Ísírẹ́lì.

26. Dáfídì ọmọ Jéṣè jẹ́ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì.

1 Kíróníkà 29