4. Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dódáì ará Áhóhì; Míkílótì jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).
5. Olórí àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. (24,000).
6. Èyí ni Bénáyà náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrin àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ Rẹ̀ Ámíṣábádì jẹ́ alákóso lórí ìpín tirẹ̀.
7. Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Ásáhélì arákùnrin Jóábù: ọmọ Rẹ̀ Ṣébádáyà jẹ́ arọ́pò Rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
8. Ẹ̀káàrún fún oṣù kárùn-ún, jẹ́ olórí Ṣámíhútì ará Íṣíráhì. Ẹgbàá méjìlá ọkùnrin (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀.
9. Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Írà ọmọ Íkéṣì, ará Tékóì. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
10. Ẹ̀kéje fún oṣù kéje jẹ́ Hélésì ará Pélónì, ará Éfíráímù. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín Rẹ̀.
11. Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Ṣíbékáì ará Húṣátì, ará Ṣéráhì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.
12. Ẹ̀kẹsàn-án fún oṣù kẹ́sàn-án jẹ́. Ábíésérì ará Ánátótì, ará Bénjámínì ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín Rẹ̀.