1 Kíróníkà 18:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó fi Gárísónì sí Édómù, gbogbo àwọn ará Édómù sì ń sìn ní abẹ́ Dáfídì. Olúwa fún Dáfídì ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

14. Dáfídì jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn Rẹ̀.

15. Jóábù ọmọ Ṣérúyà jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun; Jéhóṣáfátì ọmọ Áhílúdì jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16. Ṣádókù ọmọ Áhítúbì àti Áhímélékì ọmọ Ábíátarì jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣáfíṣà jẹ́ akọ̀wé;

1 Kíróníkà 18