1 Kíróníkà 1:42-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Àwọn ọmọ Èsérì:Bílíhánì, Ṣáfánì àti Jákánì.Àwọn ọmọ Díṣánì:Húsì àti Áránì.

43. Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Édómù, kí ó tó di wí pé àwọn ọba ará Ísírẹ́lì kán jẹ:Bélà ọmọ Béórì, ẹni tí orúkọ ìlú Rẹ̀ a máa jẹ́ Díníhábà.

44. Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà láti Bósírà jẹ ọba dípò Rẹ̀.

45. Nígbà tí Jóbábù sì kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.

1 Kíróníkà 1