39. Àwọn ọmọ Lótanì:Hórì àti Hómámù. Tímínà sì jẹ́ arábìnrin Lótanì.
40. Àwọn ọmọ Ṣóbálì:Álíánì, Mánánátì, Ébálì, Ṣéfì àti Ónámù.Àwọn ọmọ Ṣíbéónì:Áíyà àti Ánà.
41. Àwọn ọmọ Ánà:Díṣónì.Àwọn ọmọ Díṣónì:Hémídánì, Éṣébánì, Ítíránì, àti Kéránì.
42. Àwọn ọmọ Èsérì:Bílíhánì, Ṣáfánì àti Jákánì.Àwọn ọmọ Díṣánì:Húsì àti Áránì.
43. Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Édómù, kí ó tó di wí pé àwọn ọba ará Ísírẹ́lì kán jẹ:Bélà ọmọ Béórì, ẹni tí orúkọ ìlú Rẹ̀ a máa jẹ́ Díníhábà.
44. Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Ṣérà láti Bósírà jẹ ọba dípò Rẹ̀.