3. Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.
4. Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan,
5. Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,