6. Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro.
7. Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi.
8. Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri.
9. Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.
10. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.