Sek 8:6-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, bi o ba ṣe iyanu li oju iyokù awọn enia yi li ọjọ wọnyi, iba jẹ iyanu li oju mi pẹlu bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

7. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Kiye si i, emi o gbà awọn enia mi kuro ni ilẹ ila-õrun, ati kuro ni ilẹ yama;

8. Emi o si mu wọn wá, nwọn o si ma gbe ãrin Jerusalemu: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, li otitọ, ati li ododo.

9. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili.

Sek 8