Sek 8:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ṣugbọn nisisiyi emi kì yio ṣe si iyokù awọn enia yi gẹgẹ bi ti ìgba atijọ wọnni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

12. Nitori irugbin yio gbilẹ: àjara yio so eso rẹ̀, ilẹ yio si hù ọ̀pọlọpọ nkan rẹ̀ jade, awọn ọrun yio si mu irì wọn wá: emi o si mu ki awọn iyokù enia yi ni gbogbo nkan wọnyi.

13. Yio si ṣe, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ egún lãrin awọn keferi, ẹnyin ile Juda, ati ile Israeli, bẹ̃li emi o gbà nyin silẹ; ẹnyin o si jẹ ibukún: ẹ má bẹ̀ru, ṣugbọn jẹ ki ọwọ nyin ki o le.

14. Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà.

15. Bẹ̃li emi si ti rò ọjọ wọnyi lati ṣe rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda: ẹ má bẹ̀ru.

16. Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni.

17. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi.

18. Ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tọ̀ mi wá wipe,

19. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia.

Sek 8