Sek 2:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi.

11. Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ.

12. Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu.

13. Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.

Sek 2