Sek 10:10-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Emi o si tún mu wọn pada kuro ni ilẹ Egipti pẹlu, emi o si ṣà wọn jọ kuro ni ilẹ Assiria: emi o si mu wọn wá si ilẹ Gileadi ati Lebanoni; a kì yio si ri àye fun wọn.

11. Yio si là okun wahala ja, yio si lù riru omi ninu okun, gbogbo ibu odò ni yio si gbẹ, a o si rẹ̀ igberaga Assiria silẹ, ọpa alade Egipti yio si lọ kuro.

12. Emi o si mu wọn le ninu Oluwa; nwọn o si rìn soke rìn sodò li orukọ rẹ̀, ni Oluwa wi.

Sek 10