12. Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀;
13. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun.
14. Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.
15. Njẹ kini? ki awa ki o ha ma dẹṣẹ̀, nitoriti awa kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ? Ki a má ri.
16. Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo?
17. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ.
18. Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo.