Rom 11:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ṣugbọn bi a ba yà ninu awọn ẹ̀ka kuro, ti a si lọ́ iwọ, ti iṣe igi oróro igbẹ́ sara wọn, ti iwọ si mba wọn pín ninu gbòngbo ati ọra igi oróro na;

18. Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ.

19. Njẹ iwọ o wipe, A ti fà awọn ẹ̀ka na ya, nitori ki a le lọ́ mi sinu rẹ̀.

20. O dara; nitori aigbagbọ́ li a ṣe fà wọn ya kuro, iwọ si duro nipa igbagbọ́ rẹ. Máṣe gbé ara rẹ ga, ṣugbọn bẹ̀ru:

21. Nitori bi Ọlọrun kò ba da ẹ̀ka-iyẹka si, kiyesara ki o máṣe alaida iwọ na si.

22. Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro.

23. Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀.

Rom 11